Jeremaya 16:11-17 BM

11 Kí o dá wọn lóhùn pé, nítorí pé àwọn baba wọn ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé àwọn ọlọrun mìíràn, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń bọ wọ́n.

12 Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọn kò sì pa òfin mi mọ́. Ẹ̀yin gan-an ti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn baba yín lọ, ẹ wò bí olukuluku yín tí ń tẹ̀lé agídí ọkàn rẹ̀, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi.

13 Nítorí náà, n óo gba yín dànù kúrò ní ilẹ̀ yìí; n óo fọn yín dànù bí òkò, sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí. Níbẹ̀ ni ẹ óo ti máa sin oriṣa, tí ẹ óo máa bọ wọ́n tọ̀sán-tòru, nítorí pé n kò ní ṣàánú yín.”

14 Nítorí náà, OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra mọ́ pé, ‘Bí OLUWA, tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tí ń bẹ,’

15 ṣugbọn wọn yóo máa búra pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ, ẹni tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde láti ilẹ̀ àríwá ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó lé wọn lọ.’ N óo mú wọn pada sórí ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba wọn.”

16 Ó ní, “Wò ó, n óo ranṣẹ pe ọpọlọpọ apẹja, wọn yóo sì wá kó àwọn eniyan wọnyi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, n óo ranṣẹ sí ọpọlọpọ ọdẹ, wọn yóo sì wá dọdẹ wọn ní orí gbogbo òkè gíga ati àwọn òkè kéékèèké, ati ninu pàlàpálá àpáta.

17 Nítorí pé mò ń wo gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, kò sí èyí tí n kò rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò sápamọ́ fún mi.