12 OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ tíí dán olódodo wò,ìwọ tí o mọ ọkàn ati èrò eniyan.Gbẹ̀san lára wọn kí n fojú rí i,nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.
13 Ẹ kọrin sí OLUWA,ẹ yin OLUWA.Nítorí pé ó gba ẹ̀mí aláìní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi.
14 Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi,kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má jẹ́ ọjọ́ ayọ̀.
15 Ègún ni fún ẹni tí ó yọ̀ fún baba mi,tí ó sọ fún un pé,“Iyawo rẹ ti bí ọmọkunrin kan fún ọ,tí ó mú inú rẹ̀ dùn.”
16 Kí olúwarẹ̀ dàbí àwọn ìlú tí OLUWA parun láìṣàánú wọn.Kí ó gbọ́ igbe lówùúrọ̀,ati ariwo ìdágìrì lọ́sàn-án gangan.
17 Nítorí pé kò pa mí ninu oyún,kí inú ìyá mi lè jẹ́ isà òkú fún mi.Kí n wà ninu oyún ninu ìyá mi títí ayé.
18 Kí ló dé tí wọn bí mi sáyé?Ṣé kí n lè máa fojú rí ìṣẹ́ ati ìbànújẹ́ ni?Kí gbogbo ọjọ́ ayé mi lè kún fún ìtìjú?