20 Kí ni anfaani turari,tí wọn mú wá fún mi láti Ṣeba,tabi ti ọ̀pá turari olóòórùn dídùn tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè wá?N kò tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun tí ẹ mú wá siwaju mi,bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ yín kò dùn mọ́ mi.
21 Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi,wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ;ati baba, àtọmọ wọn,àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́,gbogbo wọn ni yóo parun.”
22 OLUWA ní,“Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé.
23 Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀,ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú.Ìró wọn dàbí híhó omi òkun,bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀.Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun,wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!”
24 A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ;ìdààmú dé bá wa,bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí.
25 Ẹ má lọ sinu oko,ẹ má sì ṣe rìn lójú ọ̀nà náà,nítorí ọ̀tá mú idà lọ́wọ́,ìdágìrì sì wà káàkiri.
26 Ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú;ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo;kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín.