21 Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi,wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ;ati baba, àtọmọ wọn,àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́,gbogbo wọn ni yóo parun.”
22 OLUWA ní,“Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé.
23 Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀,ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú.Ìró wọn dàbí híhó omi òkun,bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀.Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun,wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!”
24 A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ;ìdààmú dé bá wa,bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí.
25 Ẹ má lọ sinu oko,ẹ má sì ṣe rìn lójú ọ̀nà náà,nítorí ọ̀tá mú idà lọ́wọ́,ìdágìrì sì wà káàkiri.
26 Ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú;ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo;kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín.
27 Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò,o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò,o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn,kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n.