4 Nitorina sọtẹlẹ si wọn, Ọmọ enia, sọtẹlẹ.
5 Ẹmi Oluwa si bà le mi, o si wi fun mi pe, Sọ̀rọ; Bayi li Oluwa wi; Bayi li ẹnyin ti wi, Ile Israeli, nitoriti mo mọ̀ olukuluku ohun ti o wá si inu nyin.
6 Ẹnyin ti sọ okú nyin di pupọ̀ ni ilu yi, ẹnyin si ti fi okú kún igboro rẹ̀,
7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Awọn okú nyin ti ẹnyin ti tẹ́ si ãrin rẹ̀, awọn ni ẹran, ilu yi si ni ìgba; ṣugbọn emi o mu nyin jade kuro lãrin rẹ̀.
8 Oluwa Ọlọrun wipe, Ẹnyin ti bẹ̀ru idà, emi o si mu idà wa sori nyin.
9 Emi o si mu nyin kuro lãrin rẹ̀, emi o si fi nyin le awọn alejo lọwọ, emi o si mu idajọ ṣẹ si nyin lara.
10 Nipa idà li ẹnyin o ṣubu; emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.