1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe:
2 Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn woli Israeli ti nsọtẹlẹ, ki o si wi fun awọn ti nti ọkàn ara wọn sọtẹlẹ pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa;
3 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, egbé ni fun awọn aṣiwere woli, ti nwọn ntẹ̀le ẹmi ara wọn, ti wọn kò si ri nkan!
4 Israeli, awọn woli rẹ dabi kọ̀lọkọ̀lọ ni ijù,
5 Ẹnyin kò ti goke lọ si ibi ti o ya, bẹ̃ni ẹ kò si tun odi mọ fun ile Israeli lati duro li oju ogun li ọjọ Oluwa.