7 Ẹnyin kò ti ri iran asan, ẹ kò si ti fọ àfọṣẹ eke, ti ẹnyin wipe, Oluwa wi bẹ̃? bẹ̃ni emi kò sọrọ.
8 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ẹnyin ti sọ̀rọ asan, ẹnyin si ti ri eke, nitorina, kiyesi i, mo dojukọ nyin, ni Oluwa wi.
9 Ọwọ́ mi yio si wà lori awọn woli, ti nwọn ri asan, ti nwọn si nfọ àfọṣẹ eke; nwọn kì yio si ninu ijọ awọn enia mi, bẹ̃ni a kì yio kọwe wọn sinu iwe ile Israeli; bẹ̃ni nwọn kì yio wọ̀ ilẹ Israeli, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
10 Nitori, ani nitori ti nwọn ti tàn awọn enia mi wipe, Alafia; bẹ̃ni kò si alafia, ọkan si mọ ogiri, si kiyesi, awọn miran si nfi amọ̀ ti a kò pò rẹ́ ẹ.
11 Wi fun awọn ti nfi amọ̀ aipò rẹ́ ẹ, pe, yio ṣubu; òjo yio rọ̀ pupọ; ati Ẹnyin, yinyín nla, o si bọ́; ẹfũfu lile yio si ya a.
12 Kiyesi i, nigbati ogiri na ba wo, a kì yio ha wi fun nyin pe, Rirẹ́ ti ẹnyin rẹ́ ẹ ha dà?
13 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o tilẹ fi ẹfũfu lile ya a ni irúnu mi; òjo yio si rọ̀ pupọ ni ibinu mi, ati yinyin nla ni irúnu mi lati run u.