36 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti a dà ẹgbin rẹ jade, ti a si ri ihoho rẹ nipa panṣaga rẹ pẹlu awọn olufẹ rẹ, ati pẹlu gbogbo oriṣa irira rẹ, ati nipa ẹjẹ awọn ọmọ rẹ, ti iwọ fi fun wọn:
37 Si kiye si i, Emi o kó gbogbo awọn olufẹ rẹ jọ, awọn ẹniti iwọ ti ba jaiye, ati gbogbo awọn ti iwọ ti fẹ, pẹlu gbogbo awọn ti iwọ ti korira; ani emi o gbá wọn jọ kakiri si ọ, emi o si fi ihoho rẹ hàn wọn, ki nwọn ki o le ri gbogbo ihoho rẹ.
38 Emi o si dá ọ lẹjọ, gẹgẹ bi a ti da awọn obinrin lẹjọ ti o ba igbeyawo jẹ ti nwọn si ta ẹjẹ silẹ; emi o si fi ẹjẹ fun ọ, ni irúnu ati ni ijowu.
39 Emi o si fi ọ le wọn lọwọ pẹlu, nwọn o si wo ibi giga rẹ, nwọn o si wo ibi giga rẹ palẹ: nwọn o si bọ aṣọ rẹ pẹlu, nwọn o si gbà ohun ọṣọ rẹ didara, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho, ati ni goloto.
40 Nwọn o mu ẹgbẹ́ kan wá si ọ pẹlu, nwọn o si sọ ọ li okuta, nwọn o si fi idà wọn gún ọ yọ.
41 Nwọn o si fi iná kun gbogbo ile rẹ; nwọn o si mu idajọ ṣẹ si ọ lara niwaju obinrin pupọ; emi o si jẹ ki o fi panṣaga rẹ mọ, iwọ pẹlu kì yio si funni ni ọ̀ya mọ.
42 Bẹ̃ni emi o jẹ ki irúnu mi si ọ ki o dá, owú mi yio si kuro lọdọ rẹ, emi o si dakẹjẹ, emi kì yio binu mọ.