55 Nigbati awọn arabinrin rẹ Sodomu, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ba pada si ipò wọn iṣaju, ti Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin ba pada si ipò wọn iṣaju, nigbana ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin yio pada si ipò nyin iṣaju.
56 Nitori ẹnu rẹ kò da orukọ Sodomu arabinrin rẹ li ọjọ irera rẹ,
57 Ki a to ri ìwa buburu rẹ, bi akoko ti awọn ọmọbinrin Siria gàn ọ, ati gbogbo awọn ti o wà yi i ka, awọn ọmọbinrin Filistia ti o gàn ọ ka kiri.
58 Iwọ ti ru ifẹkufẹ rẹ ati ohun irira rẹ, ni Oluwa wi.
59 Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Emi o tilẹ ba ọ lò gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, ti iwọ ti gàn ibura nipa biba majẹmu jẹ.
60 Ṣugbọn emi o ranti majẹmu mi pẹlu rẹ, ni ọjọ ewe rẹ, emi o si gbe majẹmu aiyeraiye kalẹ fun ọ.
61 Iwọ o si ranti ọ̀na rẹ, oju o si tì ọ, nigbati iwọ ba gba awọn arabinrin rẹ, ẹgbọ́n rẹ ati aburò rẹ: emi o si fi wọn fun ọ bi ọmọbinrin, ṣugbọn ki iṣe nipa majẹmu rẹ.