14 Ki ijọba na le jẹ alailọla, ki o má le gbe ara rẹ̀ soke, ki o le duro nipa pipa majẹmu rẹ̀ mọ.
15 Ṣugbọn on ṣọ̀tẹ si i ni rirán awọn ikọ̀ rẹ̀ lọ si Egipti, ki nwọn ki o le fi ẹṣin fun u ati enia pupọ. Yio ha sàn a? ẹniti nṣe iru nkan wọnyi yio ha bọ́? tabi yio dalẹ tan ki o si bọ́?
16 Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nitotọ ibi ti ọba ngbe ti o fi i jọba, ibura ẹniti o gàn, majẹmu ẹniti o si bajẹ, ani lọdọ rẹ̀ lãrin Babiloni ni yio kú.
17 Bẹ̃ni Farao ti on ti ogun rẹ̀ ti o li agbara ati ẹgbẹ́ nla kì yio ṣe fun u ninu ogun, nipa mimọ odi, ati kikọle iṣọ́ ti o li agbara, lati ke enia pupọ̀ kuro:
18 Nitoriti o gàn ibura nipa didalẹ, kiye si i, o ti fi ọwọ́ rẹ̀ fun ni, o si ti ṣe gbogbo nkan wọnyi, kì yio bọ́.
19 Nitorina bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi mo ti wà, dajudaju ibura mi ti o ti gàn, ati majẹmu mi ti o ti dà, ani on li emi o san si ori on tikalarẹ̀.
20 Emi o si nà àwọn mi si i lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi; emi o si mu u de Babiloni, emi o si ba a rojọ nibẹ, nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti da si mi.