8 Ilẹ rere lẹba omi nla ni a gbìn i si, ki o le bà yọ ẹka jade, ki o si le so eso, ki o le jẹ́ àjara rere.
9 Wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; yio ha gbà? on kì yio hú gbòngbo rẹ̀, kì yio si ka eso rẹ̀ kuro, ki o le rọ? yio rọ ninu gbogbo ewe rirú rẹ̀, ani laisi agbara nla tabi enia pupọ̀ lati fà a tu pẹlu gbòngbo rẹ̀.
10 Nitõtọ, kiye si i, bi a ti gbìn i yi, yio ha gbà? kì yio ha rẹ̀ patapata? nigbati afẹfẹ ilà-õrun ba kàn a? yio rẹ̀ ninu aporo ti o ti hù.
11 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
12 Sọ nisisiyi fun ọlọ̀tẹ ile na pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohun ti nkan wọnyi jasi? Sọ fun wọn, kiyesi i, ọba Babiloni de Jerusalemu, o si ti mu ọba ibẹ ati awọn ọmọ-alade ibẹ, o si mu wọn pẹlu rẹ̀ lọ si Babiloni:
13 O si ti mu ninu iru-ọmọ ọba, o si bá a dá majẹmu, o si ti mu u bura: o si mu awọn alagbara ilẹ na pẹlu:
14 Ki ijọba na le jẹ alailọla, ki o má le gbe ara rẹ̀ soke, ki o le duro nipa pipa majẹmu rẹ̀ mọ.