1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2 Kini ẹnyin rò ti ẹnyin fi npowe yi niti ilẹ Israeli, pe, Awọn baba ti jẹ eso àjara kíkan, ehin awọn ọmọ si kan.
3 Oluwa Ọlọrun wipe, bi mo ti wà, ẹnyin kì yio ri àye lati powe yi mọ ni ilẹ Israeli.
4 Kiye si i, gbogbo ọkàn ni t'emi; gẹgẹ bi ọkàn baba ti jẹ t'emi, bẹ̃ni t'emi ni ọkàn ọmọ pẹlu; ọkàn ti o bá ṣẹ̀, on o kú.
5 Ṣugbọn bi enia kan ba ṣe olõtọ, ti o si ṣe eyiti o tọ ati eyiti o yẹ,
6 Ti kò si jẹun lori oke, ti kò si gbe oju rẹ̀ soke si awọn oriṣa ile Israeli, ti kò si bà obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, ti kò sì sunmọ obinrin ti o wà ninu aimọ́ rẹ̀.