12 Ti o ti ni talaka ati alaini lara; ti o ti fi agbara koni, ti kò mu ohun ògo pada, ti o ti gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa, ti o ti ṣe ohun irira,
13 Ti o ti fi fun ni lati gba ẹdá, ti o si ti gba èle: on o ha yè bẹ̃? on ki yio yè: on ti ṣe gbogbo ohun irira wọnyi; kikú ni yio kú: ẹjẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀.
14 Si kiye si i, bi o ba bi ọmọkunrin ti o ri gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si bẹ̀ru, ti kò si ṣe iru rẹ̀,
15 Ti kò si jẹun lori oke, ti kò gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa ile Israeli, ti kò ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ,
16 Ti kò ni ẹnikan lara, ti kò dá ohun ògo duro, ti kò fi agbara koni, ṣugbọn ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹ̀wu bo ẹni-ihoho,
17 Ti o ti mu ọwọ́ rẹ̀ kuro lara ẹni-inilara, ti kò ti gba ẹdá tabi elé ti o ti mu idajọ mi ṣẹ, ti o ti rìn ninu aṣẹ mi; on kì yio kú nitori aiṣedẽde baba rẹ̀, yiyè ni yio yè.
18 Bi o ṣe ti baba rẹ̀, nitoripe o fi ikà ninilara, ti o fi agbara ko arakunrin rẹ̀; ti o ṣe eyiti kò dara lãrin enia rẹ̀, kiye si i, on o tilẹ kú ninu aiṣedẽde rẹ̀.