20 Ọkàn ti o ba ṣẹ̀, on o kú. Ọmọ kì yio rù aiṣedẽde baba, bẹ̃ni baba kì yio rù aiṣedẽde ọmọ: ododo olododo yio wà lori rẹ̀, ìwa buburu enia buburu yio si wà lori rẹ̀.
21 Ṣugbọn bi enia buburu yio ba yipada kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ti o si pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ṣe eyi ti o tọ́, ati eyiti o yẹ, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.
22 Gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, a kì yio ranti wọn si i: ninu ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni on o yè.
23 Emi ha ni inu-didùn rara pe ki enia buburu ki o kú? ni Oluwa Ọlọrun wi: kò ṣepe ki o yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, ki o si yè?
24 Ṣugbọn nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedede, ti o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo irira ti enia buburu nṣe, on o ha yè? gbogbo ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni a kì yio ranti: ninu irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ninu wọn ni yio kú.
25 Ṣugbọn ẹnyin wipe, ọ̀na Oluwa kò gún. Gbọ́ nisisiyi, iwọ ile Israeli; ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?
26 Nigbati olododo kan ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedẽde, ti o si kú ninu wọn; nitori aiṣedẽde rẹ̀ ti o ti ṣe ni yio kú.