10 Mo si jẹ ki wọn lọ kuro ni ilẹ Egipti, mo si mu wọn wá si aginju.
11 Mo si fi aṣẹ mi fun wọn, mo si fi idajọ mi hàn wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn.
12 Pẹlupẹlu mo si fun wọn ni ọjọ isimi mi, lati ṣe àmi lãrin t'emi ti wọn, ki nwọn ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa ti o yà wọn si mimọ́.
13 Ṣugbọn ile Israeli ṣọ̀tẹ si mi ni aginjù: nwọn kò rìn ni aṣẹ mi, nwọn si gàn idajọ mi, eyiti bi enia kan ba ṣe, on o tilẹ yè ninu wọn; ati ọjọ isimi mi ni wọn tilẹ bajẹ gidigidi: nigbana ni mo wipe, emi o dà irúnu mi si wọn lori li aginju, lati pa wọn run.
14 Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má ba di ibajẹ niwaju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade.
15 Pẹlupẹlu mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn ni aginju pe emi kò ni mu wọn de ilẹ ti mo ti fi fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ;
16 Nitoriti nwọn gàn idajọ mi, nwọn kò si rìn ninu aṣẹ mi, ṣugbọn nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: nitoripe ọkàn wọn tẹ̀le oriṣa wọn.