2 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
3 Ọmọ enia, sọ fun awọn àgba Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Lati bere lọwọ mi ni ẹ ṣe wá? Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere.
4 Iwọ o ha dá wọn lẹjọ bi, ọmọ enia, iwọ o ha da wọn lẹjọ? jẹ ki wọn mọ̀ ohun-irira baba wọn.
5 Si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ni ọjọ na nigbati mo yàn Israeli, ti mo si gbe ọwọ́ mi soke si iru-ọmọ ile Jakobu, ti mo si sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn ni ilẹ Egipti, nigbati mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, wipe, Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin:
6 Ni ọjọ ti mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti si ilẹ ti mo ti wò silẹ fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ.
7 Mo si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ninu nyin gbe irira oju rẹ̀ junù, ẹ má si ṣe fi oriṣa Egipti sọ ara nyin di aimọ́: emi ni Oluwa Ọlọrun nyin.
8 Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si mi, nwọn kò si fẹ fi eti si mi: olukuluku wọn kò gbe ohun-irira oju wọn junù, bẹ̃ni nwọn kò kọ oriṣa Egipti silẹ: nigbana ni mo wipe, emi o da irúnu mi si wọn lori, lati pari ibinu mi si wọn lãrin ilẹ Egipti.