16 A o si sọ ọ di aìlọwọ ninu ara rẹ loju awọn keferi, iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
17 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
18 Ọmọ enia, ile Israeli di idarọ si mi: gbogbo wọn jẹ idẹ, ati tánganran, ati irin, ati ojé, lãrin ileru; ani nwọn jẹ idarọ fadaka.
19 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti gbogbo nyin di idarọ, kiyesi i, nitorina emi o ko nyin jọ si ãrin Jerusalemu.
20 Gẹgẹ bi nwọn ti ima ko fadaka, ati idẹ, ati irin, ati ojé, ati tánganran jọ si ãrin ileru, lati fin iná si i, ki a lè yọ́ ọ, bẹ̃ni emi o kó nyin ni ibinu mi, ati irúnu mi, emi o si fi nyin sibẹ emi o yọ́ nyin.
21 Nitotọ, emi o ko nyin jọ, emi o si fin iná ibinu mi si nyin lara, ẹ o si di yiyọ́ lãrin rẹ̀.
22 Bi a ti iyọ́ fadaka lãrin ileru, bẹ̃li a o yọ́ nyin lãrin rẹ̀; ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti dà irúnu mi si nyin lori.