12 O fẹ awọn ara Asiria aludugbo rẹ̀ li afẹju, awọn balogun ati awọn olori, ti a wọ̀ li aṣọ daradara, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin, gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wuni.
13 Nigbana ni mo ri pe a bà a jẹ, awọn mejeji gba ọ̀na kan.
14 Ati pe o mu ki panṣaga rẹ̀ bi si i: nitori igbati o ri awọn ọkunrin ti a ṣe li àworan sara ogiri, ere awọn ara Kaldea ti a fi ododó ṣe li àworan,
15 Ti a dì li àmure li ẹ̀gbẹ, ti nwọn ṣe aṣejù ni rirẹ lawani ori wọn, gbogbo wọn jẹ ajagun-kẹkẹ́ ti a ba ma wò, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Babiloni ti Kaldea, ilẹ ibi wọn:
16 Bi o si ti fi oju rẹ̀ ri wọn, o fẹ wọn li afẹjù, o si ran onṣẹ si wọn si Kaldea.
17 Awọn ara Babiloni si tọ̀ ọ wá lori akete ifẹ, nwọn si fi panṣaga wọn bà a jẹ, a si bà a jẹ pẹlu wọn, ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ wọn.
18 Bayi li o tú idi panṣaga rẹ̀ silẹ, o si tú ihòho rẹ̀ silẹ: nigbana li ọkàn mi ṣi kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn mi ti ṣi kuro lọdọ ẹ̀gbọn rẹ̀.