30 Emi o ṣe gbogbo nkan wọnyi si ọ, nitori pe iwọ ti bá awọn keferi ṣe agbere lọ, ati pe iwọ ti fi oriṣa wọn bà ara rẹ jẹ́.
31 Iwọ ti rìn li ọ̀na ẹ̀gbọn rẹ, nitorina li emi o fi ago rẹ̀ le ọ lọwọ.
32 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ o mu ninu ago ẹ̀gbọn rẹ ti o jin, ti o si tobi: a o fi ọ rẹrin ẹlẹya, a o yọ ṣuti si ọ; o gbà pupọ.
33 A o fi ọti pa ọ, a o si fi ikãnu kún ọ, pẹlu ago iyanu ati idahoro, pẹlu ago Samaria ẹ̀gbọn rẹ.
34 Iwọ o tilẹ mu u, iwọ o si fi ẹnu fa ọti jade, iwọ o si fọ apãdi na, iwọ o si fà ọmú ara rẹ tu, nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi.
35 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe iwọ ti gbagbe mi ti o si ti sọ mi si ẹhìn rẹ, nitorina iwọ rù ifẹkufẹ rẹ pẹlu ati panṣaga rẹ,
36 Oluwa tun sọ fun mi pe; Ọmọ enia, iwọ o ha dá Ahola ati Aholiba lẹ́jọ? nitõtọ sọ irira wọn fun wọn;