8 Bẹ̃ni kò fi panṣaga rẹ̀ ti o mu ti Egipti wá silẹ: nitori nigba ewe rẹ̀ ni nwọn ba a sùn, nwọn si rin ọmú ìgba wundia rẹ̀, nwọn si dà panṣaga wọn si i lara.
9 Nitorina ni mo ti fi le ọwọ́ awọn olufẹ rẹ̀, le ọwọ́ awọn ara Assiria, awọn ti o fẹ li afẹju.
10 Awọn wọnyi tu ìhoho rẹ̀ silẹ: nwọn mu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nwọn si fi idà pa a: o si di ẹni-olokiki lãrin awọn obinrin; nitori pe nwọn ti mu idajọ ṣẹ si i lara.
11 Nigbati Aholiba aburo ri eyi, o wà bàjẹ ju on lọ ni ìwa ifẹkufẹ rẹ̀, ati ni panṣaga rẹ̀ ju ẹ̀gbọn rẹ̀ lọ ni panṣaga rẹ̀.
12 O fẹ awọn ara Asiria aludugbo rẹ̀ li afẹju, awọn balogun ati awọn olori, ti a wọ̀ li aṣọ daradara, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin, gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wuni.
13 Nigbana ni mo ri pe a bà a jẹ, awọn mejeji gba ọ̀na kan.
14 Ati pe o mu ki panṣaga rẹ̀ bi si i: nitori igbati o ri awọn ọkunrin ti a ṣe li àworan sara ogiri, ere awọn ara Kaldea ti a fi ododó ṣe li àworan,