1 O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣu ikini, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
2 Ọmọ enia, nitoriti Tire ti sọ̀rọ si Jerusalemu, pe, Aha, a fọ́ eyiti iṣe bode awọn orilẹ-ède: a yi i pada si mi, emi o di kikún, on di ahoro:
3 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, mo doju kọ ọ, iwọ Tire, emi o si jẹ ki orilẹ-ède pupọ dide si ọ, gẹgẹ bi okun ti igbé ríru rẹ̀ soke.
4 Nwọn o si wó odi Tire lulẹ, nwọn o si wó ile iṣọ́ rẹ̀ lulẹ; emi o si há erùpẹ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, emi o si ṣe e bi ori apata.
5 Yio jẹ ibi ninà awọ̀n si lãrin okun: nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi: yio si di ikogun fun awọn orilẹ-ède.
6 Ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ ti o wà li oko, li a o fi idà pa; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.