3 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, mo doju kọ ọ, iwọ Tire, emi o si jẹ ki orilẹ-ède pupọ dide si ọ, gẹgẹ bi okun ti igbé ríru rẹ̀ soke.
4 Nwọn o si wó odi Tire lulẹ, nwọn o si wó ile iṣọ́ rẹ̀ lulẹ; emi o si há erùpẹ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, emi o si ṣe e bi ori apata.
5 Yio jẹ ibi ninà awọ̀n si lãrin okun: nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi: yio si di ikogun fun awọn orilẹ-ède.
6 Ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ ti o wà li oko, li a o fi idà pa; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
7 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu Nebukadnessari ọba Babiloni, ọba awọn ọba, wá si Tire, lati ariwa, pẹlu ẹṣin, ati kẹkẹ́ ogun, ati ẹlẹṣin, ati ẹgbẹ́, ati enia pupọ.
8 Yio fi idà pa awọn ọmọbinrin rẹ li oko: yio si kọ kũkũ tì ọ, yio si mọ odi tì ọ, yio si gbe apata soke si ọ.
9 Yio si gbe ohun-ẹrọ ogun tì odi rẹ, yio si fi ãke rẹ̀ wó ile-iṣọ́ rẹ lulẹ.