10 Awọn ti Persia, ati ti Ludi, ati ti Futi, wà ninu ogun rẹ, awọn ologun rẹ: nwọn fi apata ati ìbori-ogun kọ́ ninu rẹ; nwọn fi ẹwà rẹ hàn.
11 Awọn enia Arfadi, pẹlu awọn ogun rẹ, wà lori odi rẹ yika, ati awọn akọ-jamã wà ni ile-iṣọ rẹ: nwọn fi apata kọ́ sara odi rẹ yika; nwọn ti ṣe ẹwà rẹ pé.
12 Tarṣiṣi ni oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ; pẹlu fadakà, irin, tánganran, ati ojé, nwọn ti ṣòwo li ọja rẹ.
13 Jafani, Tubali, ati Meṣeki, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn ti fi ẹrú ati ohun-elò idẹ ṣòwo li ọjà rẹ.
14 Awọn ti ile Togarma fi ẹṣin, ati ẹlẹṣin ati ibaka ṣòwo li ọjà rẹ.
15 Awọn enia Dedani li awọn oniṣòwo rẹ; ọ̀pọlọpọ erekuṣu ni mba ọ ṣòwo, nwọn mu ehin-erin ati igi eboni wá fun ọ lati rà.
16 Siria li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ iṣẹ ọwọ́ rẹ: nwọn ntà emeraldi li ọjà rẹ, pẹlu purpili, ati iṣẹ oniṣẹ-ọnà, ati ọ̀gbọ daradara, ati iyùn, ati agate.