11 Awọn enia Arfadi, pẹlu awọn ogun rẹ, wà lori odi rẹ yika, ati awọn akọ-jamã wà ni ile-iṣọ rẹ: nwọn fi apata kọ́ sara odi rẹ yika; nwọn ti ṣe ẹwà rẹ pé.
12 Tarṣiṣi ni oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ; pẹlu fadakà, irin, tánganran, ati ojé, nwọn ti ṣòwo li ọja rẹ.
13 Jafani, Tubali, ati Meṣeki, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn ti fi ẹrú ati ohun-elò idẹ ṣòwo li ọjà rẹ.
14 Awọn ti ile Togarma fi ẹṣin, ati ẹlẹṣin ati ibaka ṣòwo li ọjà rẹ.
15 Awọn enia Dedani li awọn oniṣòwo rẹ; ọ̀pọlọpọ erekuṣu ni mba ọ ṣòwo, nwọn mu ehin-erin ati igi eboni wá fun ọ lati rà.
16 Siria li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ iṣẹ ọwọ́ rẹ: nwọn ntà emeraldi li ọjà rẹ, pẹlu purpili, ati iṣẹ oniṣẹ-ọnà, ati ọ̀gbọ daradara, ati iyùn, ati agate.
17 Juda, ati ilẹ Israeli, awọn li awọn oniṣòwo rẹ, alikama ti Minniti, ati Pannagi, ati oyin, ati ororo, ati balmu, ni nwọn fi ná ọjà rẹ.