2 Nisisiyi, iwọ ọmọ enia, pohunrere ẹkun fun Tire;
3 Ki o si wi fun Tire pe, Iwọ ti a tẹ̀do si ẹnu-ọ̀na okun, oniṣòwo awọn orilẹ-ède fun ọ̀pọlọpọ erekùṣu, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ Tire, iwọ ti wipe, emi pé li ẹwà.
4 Àlà rẹ wà li ãrin okun, awọn ọ̀mọle rẹ ti mu ẹwà rẹ pé.
5 Nwọn ti fi apako firi ti Seniri kàn gbogbo ọkọ̀ rẹ, nwọn ti mu kedari ti Lebanoni wá lati fi ṣe opó ọkọ̀ fun ọ.
6 Ninu igi oaku ti Baṣani ni nwọn ti fi gbẹ́ àjẹ rẹ; ijoko rẹ ni nwọn fi ehin-erin ṣe pelu igi boksi lati erekuṣu Kittimu wá.
7 Ọ̀gbọ daradara iṣẹ-ọnà lati Egipti wá li eyiti iwọ ta fi ṣe igbokun rẹ; aṣọ aláro ati purpili lati erekusu Eliṣa wá li eyiti a fi bò ọ.
8 Awọn ara ilu Sidoni ati Arfadi ni awọn ara ọkọ̀ rẹ̀: awọn ọlọgbọn rẹ, Iwọ Tire, ti o wà ninu rẹ, li awọn atọkọ̀ rẹ.