26 Awọn atukọ̀ rẹ ti mu ọ wá sinu omi nla: ẹfũfu ilà-õrun ti fọ́ ọ li ãrin okun.
27 Ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹ, ọjà tità rẹ, awọn atukọ̀ rẹ, ati atọ́kọ̀ rẹ, adikọ̀ rẹ, ati awọn alábarà rẹ, ati gbogbo awọn ologun rẹ, ti o wà ninu rẹ, ati ninu gbogbo ẹgbẹ́ rẹ, ti o wà li ãrin rẹ, yio ṣubu li ãrin okun li ọjọ iparun rẹ.
28 Awọn ilẹ àgbègbe yio mì nitori iró igbe awọn atọkọ̀ rẹ.
29 Gbogbo awọn alajẹ̀, awọn atukọ̀, ati awọn atọ́kọ̀ okun yio sọkalẹ kuro ninu ọkọ̀ wọn, nwọn o duro lori ilẹ.
30 Nwọn o si jẹ ki a gbọ́ ohùn wọn si ọ, nwọn o si kigbe kikoro, nwọn o si kù ekuru sori ara wọn, nwọn o si yi ara wọn ninu ẽru:
31 Nwọn o si fari wọn patapata fun ọ, nwọn o si fi aṣọ-àpo di ara wọn, nwọn o si sọkun fun ọ ni ikorò aiya, pẹlu ohùnrére ẹkun kikorò.
32 Ati ninu arò wọn ni nwọn o si pohùnrére ẹkún fun ọ, nwọn o si pohùnrére ẹkún sori rẹ, wipe, Ta li o dabi Tire, eyiti a parun li ãrin okun?