1 O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kẹta, li ọjọ ekini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
2 Ọmọ enia, sọ fun Farao ọba Egipti, ati fun ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ pe, Tani iwọ jọ ni titobi rẹ?
3 Kiyesi i, awọn ara Assiria ni igi kedari ni Lebanoni ti o li ẹ̀ka daradara, ti o si ṣiji boni, ti o si ga, ṣonṣo ori rẹ̀ si wà lãrin awọn ẹ̀ka bibò.
4 Omi sọ ọ di nla, ibú gbé e ga soke, o fi awọn odò nla rẹ̀ yi oko rẹ̀ ka, o si rán awọn odo kékèké rẹ̀ si gbogbo igbẹ́.
5 Nitorina a gbe giga rẹ̀ soke jù gbogbo igi igbẹ́ lọ, ẹ̀ka rẹ̀ si di pupọ̀, awọn ẹ̀ka rẹ̀ si di gigùn nitori ọ̀pọlọpọ omi, nigbati o yọ wọn jade.
6 Gbogbo ẹiyẹ oju ọrun kọ́ itẹ́ wọn ninu ẹ̀ka rẹ̀, ati labẹ ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ bi ọmọ wọn si, ati labẹ ojiji rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ède nla ngbe.
7 Bayi li o ni ẹwà ninu titobi rẹ̀, ninu gigùn ẹ̀ka rẹ̀: nitori ti egbò rẹ̀ wà li ẹbá omi nla.