8 Awọn igi kedari inu ọgbà Ọlọrun kò le bò o mọlẹ: awọn igi firi kò dabi ẹ̀ka rẹ̀, awọn igi kẹsnuti kò si dabi ẹ̀ka rẹ̀; bẹ̃ni kò si igikigi ninu ọgbà Ọlọrun ti o dabi rẹ̀ li ẹwà rẹ̀.
9 Emi ti ṣe e ni ẹwà nipa ọ̀pọlọpọ ẹ̀ka rẹ̀: tobẹ̃ ti gbogbo igi Edeni, ti o wà ninu ọgbà Ọlọrun, ṣe ilara rẹ̀.
10 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti on gbe ara rẹ̀ soke ni giga, o si ti yọ ṣonṣo rẹ̀ soke lãrin awọn ẹ̀ka didí, ọkàn rẹ̀ si gbe soke nitori giga rẹ̀;
11 Nitorina li emi ti ṣe fi i le alagbara awọn keferi lọwọ; on o bá a ṣe dajudaju: Emi ti lé e jade nitori buburu rẹ̀.
12 Ati awọn alejo, ẹlérù awọn orilẹ-ède, ti ké e kuro, nwọn si ti tú u ká; ẹka rẹ̀ ṣubu sori awọn oke, ati ninu gbogbo afonifoji, ẹka rẹ̀ si ṣẹ́ lẹba gbogbo odò ilẹ na; gbogbo awọn orilẹ-ède aiye si jade lọ kuro labẹ òjiji rẹ̀, nwọn si fi i silẹ.
13 Gbogbo awọn ẹiyẹ oju ọrun yio ma gbe ori ahoro rẹ̀, ati lori ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ yio wà.
14 Nitori ki igikigi ti o wà lẹba omi ki o má ba gbe ara wọn ga nitori giga wọn, tabi ki nwọn yọ ṣonṣo wọn lãrin ẹ̀ka dídi; tabi ki igi wọn duro ni giga wọn, gbogbo awọn ti o mu omi: nitori ti a fi gbogbo wọn le ikú lọwọ, si isalẹ aiye, li ãrin awọn ọmọ enia, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.