1 O si ṣe li ọdun kejila, li oṣù kejila, li ọjọ ikini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
2 Ọmọ enia, pohunrére fun Farao ọba Egipti, si wi fun u pe, Iwọ dabi ẹgbọ̀rọ kiniun awọn orilẹ-ède, iwọ si dabi dragoni ninu okun, iwọ si jade wá pẹlu awọn odò rẹ, iwọ ti fi ẹsẹ rẹ rú omi, o si ti bà awọn odò wọn jẹ́.
3 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitorina emi o nà àwọn mi sori rẹ pẹlu ẹgbẹ́ enia pupọ̀; nwọn o si fà ọ goke ninu àwọn mi.
4 Nigbana ni emi o fi ọ silẹ lori ilẹ, emi o gbe ọ sọ sinu igbẹ́, emi o mu ki gbogbo awọn ẹiyẹ oju ọrun ba le ọ lori, emi o si fi ọ bọ́ gbogbo awọn ẹranko aiye.
5 Emi o gbe ẹran ara rẹ kà awọn ori oke, gbogbo afonifoji li emi o fi giga rẹ kún.