Esek 32:24-30 YCE

24 Elamu wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti nwọn sọkalẹ li alaikọla si ìsalẹ aiye, ti o da ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye; sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

25 Nwọn ti gbe akete kan kalẹ fun u li ãrin awọn ti a pa pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka, gbogbo wọn alaikọla ti a fi idà pa: bi a tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye, sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: a fi i si ãrin awọn ti a pa.

26 Meṣeki ati Tubali wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka: gbogbo wọn alaikọlà ti a fi idà pa, bi nwọn tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye.

27 Nwọn kì yio si dubulẹ tì awọn alagbara ti o ṣubu ninu awọn alaikọlà, ti nwọn sọkalẹ lọ si ipò-okú pẹlu ihámọra ogun wọn: nwọn ti fi idà wọn rọ ori wọn, ṣugbọn aiṣedẽde wọn yio wà lori egungun wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ẹ̀ru awọn alagbara ni ilẹ alãye.

28 Lõtọ, a o fọ́ ọ lãrin awọn alaikọlà, iwọ o si dubulẹ tì awọn ti a fi idà pa.

29 Edomu wà nibẹ, awọn ọba rẹ̀, ati awọn ọmọ-alade rẹ̀, ti a tẹ́ pẹlu agbara wọn tì awọn ti a fi idà pa, nwọn o dubulẹ tì awọn alaikọlà, ati pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

30 Awọn ọmọ-alade ariwa wà nibẹ, gbogbo wọn, ati awọn ara Sidoni, ti nwọn sọkalẹ lọ pẹlu awọn ti a pa; pẹlu ẹ̀ru wọn, oju agbara wọn tì wọn; nwọn si dubulẹ li alaikọlà pẹlu awọn ti a fi idà pa, nwọn si rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.