7 Nigbati emi o ba mú ọ kuro, emi o bò ọrun, emi o si mu ki awọn ìrawọ inu rẹ̀ ṣokùnkun, emi o fi kũkũ bò õrùn, òṣupa kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn.
8 Gbogbo imọlẹ oju ọrun li emi o mu ṣokùnkun lori rẹ, emi o gbe okùnkun kà ilẹ rẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.
9 Emi o si bí ọ̀pọlọpọ enia ninu, nigbati emi o ba mu iparun rẹ wá sãrin awọn orilẹ-ède, si ilẹ ti iwọ kò ti mọ̀ ri.
10 Nitõtọ, emi o mu ki ẹnu yà ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède si ọ, awọn ọba wọn yio si bẹ̀ru gidigidi nitori rẹ, nigbati emi o ba mì idà mi niwaju wọn; nwọn o si warìri nigbagbogbo, olukuluku enia fun ẹmi ara rẹ̀, li ọjọ iṣubu rẹ.
11 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Idà ọba Babiloni yio wá sori rẹ.
12 Emi o mu ki ọ̀pọlọpọ enia rẹ ṣubu nipa idà awọn alagbara, ẹlẹ́rù awọn orilẹ-ẹ̀de ni gbogbo wọn; nwọn o si bà afẹ́ Egipti jẹ́, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ ni nwọn o parun.
13 Emi o si pa gbogbo awọn ẹranko inu rẹ̀ run kuro lẹba awọn omi nla, bẹ̃ni ẹsẹ enia kì yio rú wọn mọ́ lailai, tabi pátakò awọn ẹranko kì yio rú wọn.