5 A si tú wọn ka, nitori ti oluṣọ́ agutan kò si: nwọn si di onjẹ fun gbogbo ẹranko igbẹ́, nigbati a tú wọn ka.
6 Awọn agutàn mi ṣako ni gbogbo òke, ati lori gbogbo òke kékèké, nitõtọ, a tú ọwọ́-ẹran mi ká ilẹ gbogbo, ẹnikẹni kò bere wọn ki o si wá wọn lọ.
7 Nitorina ẹnyin oluṣọ́ agutan, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa.
8 Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ, nitori ti ọwọ́-ẹran mi di ijẹ, ti ọwọ́-ẹran mi di onjẹ fun olukuluku ẹranko igbẹ́, nitoriti kò si oluṣọ́ agutan, bẹ̃ni awọn oluṣọ́ agutan kò wá ọwọ́-ẹran mi ri, ṣugbọn awọn oluṣọ́ agutan bọ́ ara wọn, nwọn kò si bọ́ ọwọ́-ẹran mi.
9 Nitorina, ẹnyin oluṣọ́ agutan, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa;
10 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ awọn oluṣọ́ agutan; emi o si bere ọwọ́-ẹ̀ran mi lọwọ wọn, emi o si mu wọn dẹ́kun ati ma bọ́ awọn ọwọ́-ẹran: bẹ̃ni awọn ọluṣọ́ agutan kì yio bọ́ ara wọn mọ, nitori ti emi o gbà ọwọ́-ẹran mi kuro li ẹnu wọn ki nwọn ki o má ba jẹ onjẹ fun wọn.
11 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi, ani emi, o bere awọn agutan mi, emi o si wá wọn ri.