4 Nitorina, ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oke-nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, fun ibi idahoro, ati fun awọn ilu ti a kọ̀ silẹ, ti o di ijẹ ati iyọsùtisi fun awọn keferi iyokù ti o yika kiri;
5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitõtọ ninu iná owu mi li emi ti sọ̀rọ si awọn keferi iyokù, ati si gbogbo Idumea, ti o ti fi ayọ̀ inu wọn gbogbo yàn ilẹ mi ni iní wọn, pẹlu àrankan inu, lati ta a nù fun ijẹ.
6 Nitorina sọtẹlẹ niti ilẹ Israeli, ki o si wi fun awọn oke nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Wò o, emi ti sọ̀rọ ninu owu mi, ati ninu irúnu mi, nitori ti ẹnyin ti rù itiju awọn keferi.
7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi ti gbe ọwọ́ mi soke, Nitõtọ awọn keferi ti o yi nyin ka, awọn ni yio rù itiju wọn.
8 Ṣugbọn ẹnyin, oke Israeli, ẹnyin o yọ ẹka jade, ẹ o si so eso nyin fun Israeli enia mi; nitori nwọn fẹrẹ̀ de.
9 Si kiyesi i, emi wà fun nyin, emi o si yipadà si nyin, a o si ro nyin, a o si gbìn nyin:
10 Emi o si mu enia bi si i lori nyin, gbogbo ile Israeli, ani gbogbo rẹ̀: awọn ilu yio si ni olugbe, a o si kọ́ ibi ti o di ahoro: