13 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi bá ti ṣí ibojì nyin, ẹnyin enia mi, ti emi bá si mu nyin dide kuro ninu ibojì nyin.
14 Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, ẹnyin o si yè, emi o si mu nyin joko ni ilẹ ti nyin: nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ ọ, ti o si ti ṣe e, li Oluwa wi.
15 Ọrọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
16 Ati iwọ, ọmọ enia, mu igi kan, si kọwe si i lara, Fun Juda, ati fun awọn ọmọ Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀: si mu igi miran, si kọwe si i lara, Fun Josefu, igi Efraimu, ati fun gbogbo ile Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀.
17 Si dà wọn pọ̀ ṣọkan si igi kan; nwọn o si di ọkan li ọwọ́ rẹ.
18 Nigbati awọn enia rẹ ba ba ọ sọ̀rọ, wipe, Iwọ kì yio fi idi nkan wọnyi hàn wa?
19 Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu igi Josefu, ti o wà li ọwọ́ Efraimu, ati awọn ẹya Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀, emi o si mu wọn pẹlu rẹ̀, pẹlu igi Juda, emi o si sọ wọn di igi kan, nwọn o si di ọkan li ọwọ́ mi.