17 Si dà wọn pọ̀ ṣọkan si igi kan; nwọn o si di ọkan li ọwọ́ rẹ.
18 Nigbati awọn enia rẹ ba ba ọ sọ̀rọ, wipe, Iwọ kì yio fi idi nkan wọnyi hàn wa?
19 Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu igi Josefu, ti o wà li ọwọ́ Efraimu, ati awọn ẹya Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀, emi o si mu wọn pẹlu rẹ̀, pẹlu igi Juda, emi o si sọ wọn di igi kan, nwọn o si di ọkan li ọwọ́ mi.
20 Igi ti iwọ kọwe si lara yio wà li ọwọ́ rẹ, niwaju wọn.
21 Si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu awọn ọmọ Israeli kuro lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ, emi o si ṣà wọn jọ niha gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ti wọn.
22 Emi o si sọ wọn di orilẹ-ède kan ni ilẹ lori oke-nla Israeli; ọba kan ni yio si jẹ lori gbogbo wọn: nwọn kì yio si jẹ orilẹ-ède meji mọ, bẹ̃ni a kì yio sọ wọn di ijọba meji mọ rara.
23 Bẹ̃ni nwọn kì yio fi oriṣa wọn bà ara wọn jẹ mọ, tabi ohun-irira wọn, tabi ohun irekọja wọn: ṣugbọn emi o gbà wọn là kuro ninu gbogbo ibugbe wọn, nibiti nwọn ti dẹṣẹ, emi o si wẹ̀ wọn mọ́: bẹ̃ni nwọn o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.