22 Emi o si sọ wọn di orilẹ-ède kan ni ilẹ lori oke-nla Israeli; ọba kan ni yio si jẹ lori gbogbo wọn: nwọn kì yio si jẹ orilẹ-ède meji mọ, bẹ̃ni a kì yio sọ wọn di ijọba meji mọ rara.
23 Bẹ̃ni nwọn kì yio fi oriṣa wọn bà ara wọn jẹ mọ, tabi ohun-irira wọn, tabi ohun irekọja wọn: ṣugbọn emi o gbà wọn là kuro ninu gbogbo ibugbe wọn, nibiti nwọn ti dẹṣẹ, emi o si wẹ̀ wọn mọ́: bẹ̃ni nwọn o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.
24 Dafidi iranṣẹ mi yio si jẹ ọba lori wọn; gbogbo wọn ni yio si ni oluṣọ-agutan kan: nwọn o rìn ninu idajọ mi pẹlu, nwọn o si kiyesi aṣẹ mi, nwọn o si ṣe wọn.
25 Nwọn o si ma gbe ilẹ ti emi ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi, nibiti awọn baba nyin ti gbe; nwọn o si ma gbe inu rẹ̀, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ ọmọ wọn lailai: Dafidi iranṣẹ mi yio si ma jẹ ọmọ-alade wọn lailai.
26 Pẹlupẹlu emi o ba wọn dá majẹmu alafia; yio si jẹ majẹmu aiyeraiye pẹlu wọn: emi o si gbe wọn kalẹ, emi o si mu wọn rẹ̀, emi o si gbe ibi mimọ́ mi si ãrin wọn titi aiye.
27 Agọ mi yio wà pẹlu wọn: nitõtọ, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.
28 Awọn keferi yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ Israeli di mimọ́, nigbati ibi mimọ́ mi yio wà li ãrin wọn titi aiye.