Esek 38:8-14 YCE

8 Lẹhìn ọjọ pupọ̀ li a o bẹ̀ ọ wò: li ọdun ikẹhìn, iwọ o wá si ilẹ ti a gbà padà lọwọ idà, ti a si kojọ pọ̀ kuro lọdọ enia pupọ̀, lori oke-nla Israeli, ti iti ma di ahoro: ṣugbọn a mu u jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, nwọn o si ma gbe li ailewu, gbogbo wọn.

9 Iwọ o goke wá, iwọ o si de bi ijì, iwọ o dabi awọsanma lati bò ilẹ, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati ọ̀pọlọpọ enia pẹlu rẹ.

10 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; yio si ṣe pe nigbakanna ni nkan yio sọ si ọ̀kàn rẹ, iwọ o si rò èro ibi kan.

11 Iwọ o si wipe, emi o goke lọ si ilẹ ileto ti kò ni odi: emi o tọ̀ awọn ti o wà ni isimi lọ, ti nwọn ngbe laibẹ̀ru, ti gbogbo wọn ngbe laisi odi, ti nwọn kò si ni agbarà-irin tabi ẹnu-odi,

12 Lati lọ kó ikogun, ati lati lọ mu ohun ọdẹ; lati yi ọwọ́ rẹ si ibi ahoro wọnni ti a tẹ̀do nisisiyi, ati si enia ti a kojọ lati inu awọn orilẹ-ède wá, awọn ti o ti ni ohun-ọ̀sin ati ẹrù, ti ngbe oke ilẹ na.

13 Ṣeba, ati Dedani, ati awọn oniṣòwo Tarṣiṣi, pẹlu gbogbo awọn ọmọ kiniun wọn, yio si wi fun ọ pe, Ikogun ni iwọ wá kó? lati wá mu ohun ọdẹ li o ṣe gbá awọn ẹgbẹ́ rẹ jọ? lati wá rù fadaka ati wura lọ, lati wá rù ohun-ọsìn ati ẹrù, lati wá kó ikogun nla?

14 Nitorina, sọtẹlẹ, ọmọ enia, si wi fun Gogu pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ni ijọ na nigbati awọn enia mi Israeli ba ngbe laibẹ̀ru, iwọ kì yio mọ̀?