1 NITORINA, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ si Gogu, si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi dojukọ́ ọ, iwọ Gogu, olori ọmọ-alade Meṣeki ati Tubali:
2 Emi o si dá ọ padà, emi o si dári rẹ, emi o si mu ọ goke wá lati ihà ariwa, emi o si mu ọ wá sori oke giga Israeli:
3 Emi o si lù ọrun rẹ kurò li ọwọ́ osì rẹ, emi o si mu ọfà rẹ bọ kuro lọwọ ọtun rẹ.
4 Iwọ o ṣubu lori òke giga Israeli, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ: emi o fi ọ fun ẹiyẹ ọdẹ onirũru iyẹ, ati ẹranko igbẹ lati pa jẹ.
5 Iwọ o ṣubu ni gbangba oko: nitori emi li o sọ ọ, ni Oluwa Ọlọrun wi.