10 Nwọn kì yio lọ rù igi lati inu oko wá, bẹ̃ni nwọn kì yio ke igi lulẹ lati inu igbẹ́ wá; nitori ohun ihamọra ni nwọn ti fi daná; nwọn o si ko awọn ti o ko wọn, nwọn o si dọdẹ awọn ti o dọdẹ wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.
11 Yio si ṣe li ọjọ na, emi o fi ibikan fun Gogu nibẹ fun iboji ni Israeli, afonifoji awọn èro ni gabasi okun; on si pa awọn èro ni ẹnu mọ: nibẹ ni nwọn o gbe sin Gogu ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ si: nwọn o si pè e ni, Afonifoji Hamon-gogu.
12 Oṣù meje ni ile Israeli yio si ma fi sin okú wọn, ki nwọn ba le sọ ilẹ na di mimọ́.
13 Gbogbo enia ilẹ na ni yio si sin wọn: yio si jẹ okiki fun wọn li ọjọ ti a o yìn mi logo, ni Oluwa Ọlọrun wi.
14 Nwọn o si yà awọn ọkunrin sọtọ ti yio ma fi ṣe iṣẹ iṣe, lati ma rìn ilẹ na ja lati lọ isin awọn erò ti o kù lori ilẹ, lati sọ ọ di mimọ́: lẹhin oṣù meje nwọn o ma wá kiri.
15 Awọn èro ti nlà ilẹ na kọja, nigbati ẹnikan ba ri egungun enia kan, yio sàmi kan si ẹba rẹ̀, titi awọn asinku yio fi sin i si afonifoji Hamon-gogu.
16 Orukọ ilu na pẹlu yio si jẹ Hamona. Bayi ni nwọn o si sọ ilẹ na di mimọ́.