12 Oṣù meje ni ile Israeli yio si ma fi sin okú wọn, ki nwọn ba le sọ ilẹ na di mimọ́.
13 Gbogbo enia ilẹ na ni yio si sin wọn: yio si jẹ okiki fun wọn li ọjọ ti a o yìn mi logo, ni Oluwa Ọlọrun wi.
14 Nwọn o si yà awọn ọkunrin sọtọ ti yio ma fi ṣe iṣẹ iṣe, lati ma rìn ilẹ na ja lati lọ isin awọn erò ti o kù lori ilẹ, lati sọ ọ di mimọ́: lẹhin oṣù meje nwọn o ma wá kiri.
15 Awọn èro ti nlà ilẹ na kọja, nigbati ẹnikan ba ri egungun enia kan, yio sàmi kan si ẹba rẹ̀, titi awọn asinku yio fi sin i si afonifoji Hamon-gogu.
16 Orukọ ilu na pẹlu yio si jẹ Hamona. Bayi ni nwọn o si sọ ilẹ na di mimọ́.
17 Ati iwọ, ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Sọ fun olukuluku ẹiyẹ abiyẹ́, ati fun olukuluku ẹranko igbẹ, pe, Ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si wá: ẹ gbá ara nyin jọ ni ihà gbogbo si ẹbọ mi ti emi rú fun nyin, ani irubọ nla lori oke giga Israeli, ki ẹnyin ba le jẹ ẹran, ki ẹ si mu ẹjẹ.
18 Ẹnyin o jẹ ẹran-ara awọn alagbara, ẹnyin o si mu ẹjẹ awọn ọmọ-alade aiye, ti agbò, ti ọdọ agutan, ati ti obukọ, ti akọ malũ, gbogbo wọn abọpa Baṣani.