22 Ile Israeli yio si mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun wọn lati ọjọ na lọ titi.
23 Awọn keferi yio si mọ̀ pe Israeli lọ si igbekùn nitori aiṣedẽde wọn: nitoriti nwọn ti ṣọ̀tẹ si mi, nitorina ni mo ṣe fi oju mi pamọ kuro lọdọ wọn, ti mo si fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ: gbogbo wọn si ti ipa idà ṣubu.
24 Gẹgẹ bi aimọ́ wọn, ati gẹgẹ bi irekọja wọn ni mo ṣe si wọn, mo si fi oju mi pamọ́ kuro lọdọ wọn.
25 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nisisiyi li emi o mu igbèkun Jakobu padà bọ̀, emi o si ṣãnu fun gbogbo ile Israeli, emi o si jowu nitori orukọ mi mimọ́:
26 Nwọn o si rù itiju wọn, ati gbogbo ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, nigbati nwọn ngbe laibẹ̀ru ni ilẹ wọn, ti ẹnikẹni kò si dẹ̀ruba wọn.
27 Nigbati emi ti mu wọn bọ̀ lati ọdọ orilẹ-ède, ti mo si ko wọn jọ lati ilẹ awọn ọta wọn wá, ti a si yà mi si mimọ́ ninu wọn niwaju orilẹ-ède pupọ.
28 Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn, nipa kikó ti mo mu ki a kó wọn lọ si igbekun lãrin awọn keferi: ṣugbọn mo ti ṣà wọn jọ si ilẹ wọn, emi kò si fi ẹnikẹni wọn silẹ nibẹ mọ.