1 LI ọdun kẹ̃dọgbọn oko-ẹrú wa, ni ibẹ̀rẹ ọdun na, li ọjọ ikẹwa oṣù, li ọdun ikẹrinla lẹhin igbati ilu fọ́, li ọjọ na gan, ọwọ́ Oluwa wà lara mi, o si mu mi wá sibẹ na.
2 Ninu iran Ọlọrun li o mu mi wá si ilẹ Israeli, o si gbe mi ka oke giga kan, lori eyiti kikọ ilu wà ni iha gusu.
3 O si mu mi wá sibẹ, si kiyesi i, ọkunrin kan mbẹ, ẹniti irí rẹ̀ dabi irí bàba, pẹlu okùn ọ̀gbọ li ọwọ́ rẹ̀, ati ije iwọ̀nlẹ; on si duro ni ẹnu-ọ̀na.
4 Ọkunrin na si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi oju rẹ wò, ki o si fi eti rẹ gbọ́, ki o si gbe ọkàn rẹ le ohun gbogbo ti emi o fi han ọ; nitori ka ba le fi wọn han ọ li a ṣe mu ọ wá ihinyi: sọ ohun gbogbo ti o ri fun ile Israeli.
5 Si kiye si i, ogiri kan mbẹ lode ile na yika, ije iwọ̀nlẹ kan si mbẹ lọwọ ọkunrin na, igbọnwọ mẹfa, nipa igbọnwọ ati ibú atẹlẹwọ kan: o si wọ̀n ibú ile na, ije kan; ati giga rẹ̀, ije kan.
6 Nigbana li o wá si ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si gùn oke atẹ̀gun na lọ, o si wọ̀n iloro ẹnu ọ̀na, ti o jẹ ije kan ni ibú; ati iloro miran ti ẹnu-ọ̀na na, ti o jẹ ije kan ni ibú.
7 Yará kékèké si jẹ ije kan ni gigùn, ati ije kan ni ibú; ati lãrin yará kékèké igbọnwọ marun; àtẹwọ ẹnu-ọ̀na lẹba iloro ẹnu-ọ̀na ti inu si jẹ ije kan.