1 O si mu mi wá si agbala ode, li ọ̀na apa ariwa: o si mu mi wá si yará ti o kọju si ibi ti a yà sọtọ̀, ti o si kọju si ile lọna ariwa.
2 Niwaju, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn ni ilẹkun ariwa, ati ibú rẹ̀ ãdọta igbọnwọ.
3 Niwaju, ogún igbọnwọ ti o wà fun agbalá ti inu, ati niwaju itẹle ti o wà fun agbalá ti ode; ibujoko oke ti o kọju si ibujoko-oke wà ni orule mẹta.
4 Ati niwaju awọn yará ni irìn igbọnwọ mẹwa ni ibú ninu, ọ̀na igbọnwọ kan; ilẹkùn wọn si wà nihà ariwa.
5 Ati awọn yará oke kuru jù; nitori ibujoko ti awọn yará isalẹ ati yará ãrin yọ siwaju wọnyi ti ile.
6 Nitori nwọn jẹ olorule mẹta, ṣugbọn nwọn kò ni ọwọ̀n bi ọwọ̀n agbalá: nitorina a fasẹhin kuro ninu yará isalẹ ati kuro ninu yará ãrin lati ilẹ wá.