4 Ati niwaju awọn yará ni irìn igbọnwọ mẹwa ni ibú ninu, ọ̀na igbọnwọ kan; ilẹkùn wọn si wà nihà ariwa.
5 Ati awọn yará oke kuru jù; nitori ibujoko ti awọn yará isalẹ ati yará ãrin yọ siwaju wọnyi ti ile.
6 Nitori nwọn jẹ olorule mẹta, ṣugbọn nwọn kò ni ọwọ̀n bi ọwọ̀n agbalá: nitorina a fasẹhin kuro ninu yará isalẹ ati kuro ninu yará ãrin lati ilẹ wá.
7 Ati ogiri ti o wà lode ti o kọju si yará, li apa agbala ode niwaju yará, gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ.
8 Nitori gigùn awọn yará ti o wà lode jẹ ãdọta igbọnwọ: si wò o, niwaju tempili o jẹ ọgọrun igbọnwọ.
9 Ati lati isalẹ yará wọnyi ni iwọle li ọ̀na ila-õrun wà, bi a ti nlọ sinu wọn lati agbala ode wá.
10 Ni ibú ogiri agbala, li ọ̀na ila-õrun niwaju ibiti a yà sọtọ̀, ati niwaju ile na, ni awọn yará na wà.