1 O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na, ẹnu-ọ̀na ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun:
2 Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wá lati ọ̀na ila-õrun: ati ohùn rẹ̀ ri bi ariwo omi pupọ̀: aiye si ràn fun ogo rẹ̀.
3 O si dabi irí iran ti mo ri, gẹgẹ bi iran ti mo ri nigbati mo wá lati pa ilu na run: iran na si dabi iran ti mo ri lẹba odò Kebari, mo si doju mi bolẹ.
4 Ogo Oluwa si wá si ile na lati ọ̀na ilẹkùn ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun.
5 Ẹmi si gbe mi soke, o si mu mi wá si àgbala tinu: si kiye si i, ogo Oluwa kún ile na.
6 Mo si gbọ́ o mba mi sọ̀rọ lati inu ile wá; ọkunrin na si duro tì mi.
7 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, ibi itẹ mi, ati ibi atẹlẹṣẹ mi, nibiti emi o gbe lãrin awọn ọmọ Israeli lailai, ati orukọ mimọ́ mi, ni ki ile Israeli má bajẹ mọ, awọn, tabi ọba wọn, nipa panṣaga wọn, tabi nipa okú ọba wọn ni ibi giga wọn.