Esek 43:7-13 YCE

7 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, ibi itẹ mi, ati ibi atẹlẹṣẹ mi, nibiti emi o gbe lãrin awọn ọmọ Israeli lailai, ati orukọ mimọ́ mi, ni ki ile Israeli má bajẹ mọ, awọn, tabi ọba wọn, nipa panṣaga wọn, tabi nipa okú ọba wọn ni ibi giga wọn.

8 Ni titẹ́ iloro wọn nibi iloro mi, ati opó wọn nibi opó mi, ogiri si wà lãrin emi ati awọn, nwọn si ti ba orukọ mimọ́ mi jẹ nipa ohun irira wọn ti nwọn ti ṣe: mo si run wọn ni ibinu mi.

9 Njẹ ki nwọn mu panṣaga wọn, ati okú awọn ọba wọn jina kuro lọdọ mi, emi o si ma gbe ãrin wọn lailai.

10 Iwọ ọmọ enia, fi ile na hàn ile Israeli, ki oju aiṣedede wọn ba le tì wọn: si jẹ ki nwọn wọ̀n apẹrẹ na.

11 Bi oju gbogbo ohun ti nwọn ba ṣe ba si tì wọn, fi irí ile na hàn wọn, ati kikọ́ rẹ̀, ati ijade rẹ̀, ati iwọle rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo ofin rẹ̀; ki o si kọ ọ loju wọn, ki nwọn ki o lè pa gbogbo irí rẹ̀ mọ, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ki nwọn si ṣe wọn.

12 Eyi ni ofin ile na; Lori oke giga, gbogbo ipinnu rẹ̀ yika ni mimọ́ julọ. Kiyesi i, eyi ni ofin ile na.

13 Wọnyi si ni iwọ̀n pẹpẹ nipa igbọnwọ; Igbọnwọ jẹ igbọnwọ kan ati ibú atẹlẹwọ kan; isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ kan, ati igbati rẹ̀ ni eti rẹ̀ yika yio jẹ ika kan: eyi ni yio si jẹ ibi giga pẹpẹ na.