14 Emi o si ṣe wọn ni oluṣọ́ ibi-iṣọ́ ile, fun gbogbo iṣẹ rẹ̀, ati fun ohun gbogbo ti a o ṣe ninu rẹ̀.
15 Ṣugbọn awọn alufa awọn Lefi, awọn ọmọ Sadoku, ti o pa ibi-iṣọ ibi mimọ́ mi mọ, nigbati awọn ọmọ Israeli ṣìna kuro lọdọ mi, awọn ni yio sunmọ ọdọ mi lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si duro niwaju mi lati rú ọrá ati ẹjẹ si mi, ni Oluwa Ọlọrun wi:
16 Awọn ni yio wá si ibi-mimọ́ mi, awọn ni o si sunmọ tabili mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si pa ibi-iṣọ́ mi mọ́.
17 Yio si ṣe pe, nigbati nwọn ba wá si ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, nwọn o wọ̀ ẹ̀wu ọ̀gbọ; irun agutan kì yio bọ́ si ara wọn, nigbati nwọn ba nṣe iranṣẹ ni ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, ati ninu ile.
18 Nwọn o si ni filà ọ̀gbọ li ori wọn, ṣòkoto ọ̀gbọ ni nwọn o si wọ̀ ni idí wọn; nwọn kì o si fi ohun ti imuni lãgùn dì amurè.
19 Nigbati nwọn ba si lọ si agbalá ode, ani si agbalá ode sọdọ awọn enia, nwọn o bọ́ ẹ̀wu wọn ti wọn ifi ṣe iranṣẹ, nwọn o si fi wọn si awọn yará mimọ́, nwọn o si wọ̀ ẹ̀wu miran; nwọn kì yio si fi ẹ̀wu wọn sọ awọn enia di mimọ́.
20 Nwọn kì o si fá ori wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio jẹ ki irun wọn gbọ̀; ni rirẹ nwọn o rẹ irun ori wọn.