20 Nwọn kì o si fá ori wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio jẹ ki irun wọn gbọ̀; ni rirẹ nwọn o rẹ irun ori wọn.
21 Alufa gbogbo kì yio mu ọti-waini, nigbati nwọn ba wá si agbalá ti inu.
22 Nwọn kì yio si fẹ́ opo, tabi ẹniti a tì jade fun aya wọn: ṣugbọn nwọn o fẹ́ wundia lati iru-ọmọ ile Israeli, tabi opo ti o ti ni alufa ri.
23 Nwọn o si kọ́ awọn enia mi ni iyàtọ ti o wà lãrin mimọ́ ati ailọ̀wọ, nwọn o si mu wọn mọ̀ eyiti o wà lãrin aimọ́ ati mimọ́.
24 Ati ni ija, awọn ni yio duro lati ṣe idajọ; nwọn o si dá a ni idajọ mi: nwọn o si pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́ ni gbogbo apejọ mi; nwọn o si yà awọn ọjọ isimi mi si mimọ́.
25 Nwọn kì yio si wá sọdọ okú enia lati sọ ara wọn di aimọ́, ṣugbọn fun baba, tabi fun iya, tabi fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, fun arakunrin, tabi fun arabinrin ti kò ti ni ọkọ, nwọn le sọ ara wọn di aimọ́.
26 Ati lẹhin iwẹnumọ́ rẹ̀, nwọn o si ká ọjọ meje fun u.