4 Eyi ti o mọ́ ninu ilẹ na yio jẹ ti awọn alufa, awọn iranṣẹ ibi-mimọ́, ti yio sunmọ lati ṣe iránṣẹ fun Oluwa: yio si jẹ àye fun ile wọn, ati ibi-mimọ́ fun ibi-mimọ́.
5 Ati ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigun, ati ti ẹgbãrun ni ibú, ni awọn Lefi, pẹlu awọn iranṣẹ ile na, ni ogún yará, fun ara wọn, ni ini.
6 Ati ini ilu na li ẹnyin o yàn ẹgbarun ni ibú, ati ẹgba mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, lẹba ọrẹ ipín mimọ́ na: yio jẹ ti gbogbo ile Israeli.
7 Ati ipín kan yio jẹ ti olori nihà kan ati niha keji ọrẹ ipin mimọ́, ati ti ini ilu, ti o kọju si ọrẹ ipín mimọ́, ti o si kọju si iní ti ilu, lati iha iwọ-õrun si iwọ-õrun, ati lati ihà ila-õrun si ila-õrun: gigùn rẹ̀ yio gbe ọkan ninu awọn ipín, lati eti iwọ-õrun de eti ila-õrun.
8 Ni ilẹ na ni iní rẹ̀ yio wà ni Israeli: awọn olori mi kì yio si ni awọn enia mi lara mọ́; ati ilẹ iyokù ni nwọn o fi fun ile Israeli gẹgẹ bi ẹyà wọn.
9 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ki o to fun nyin, ẹnyin olori Israeli: ẹ mu ìwa ipa irẹ́jẹ kuro, ki ẹ si mu idajọ ati ododo ṣẹ, mu ilọ́nilọwọgbà nyin kuro lọdọ awọn enia mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.
10 Ki ẹnyin ki o ni ìwọn títọ, ati efà títọ, ati bati títọ.