15 Bayi ni nwọn o pèse ọdọ-agutan na, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ na, ati ororo na, lojojumọ fun ọrẹ-ẹbọ sisun nigbagbogbo.
16 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi olori na ba fi ẹbùn fun ẹnikẹni ninu awọn ọmọ rẹ̀, ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀; yio jẹ ini wọn nipa ijogun.
17 Bi o ba si fi ẹbùn ninu ini rẹ̀ fun ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, nigbana yio jẹ tirẹ̀ titi di ọdun omnira; yio si tun pada di ti olori na: ṣugbọn ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀ fun wọn.
18 Olori na kì yio si fi ipá mu ninu ogún awọn enia lati le wọn jade kuro ninu ini wọn, yio fi ogún fun awọn ọmọ rẹ̀ lara ini ti ontikalarẹ̀: ki awọn enia mi ki o má ba tuká, olukuluku kuro ni ini rẹ̀.
19 O si mu mi kọja li abawọ̀, ti o wà lẹba ẹnu-ọ̀na, si awọn yará mimọ́ ti awọn alufa, ti o kọjusi ariwa: si kiyesi i, ibi kan wà nibẹ̀ ni ihà mejeji iwọ-õrun.
20 O si wi fun mi pe, Eyi ni ibiti awọn alufa yio ma sè ọrẹ irekọja ati ọrẹ ẹ̀ṣẹ, nibiti nwọn o ma yan ọrẹ jijẹ; ki nwọn má ba gbe wọn jade si agbalá ode, lati sọ awọn enia di mimọ́.
21 O si mu mi jade wá si agbalá ode, o si mu mi kọja ni igun mẹrẹrin agbalá na; si kiyesi i, ni olukuluku igun agbalá na ni agbala kan gbe wà.